12 Nígbà tí a sì gúnlẹ̀ ní Sírákúsì, a gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.
13 Láti ibẹ̀ nígbà tí a lọ yíká; a dé Régíónì: nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, afẹ́fẹ́ gúsù bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́, ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Pútéólì.
14 A sì rí àwọn arákùnrin kan níbẹ̀, tí wọ́n sì bẹ́ wá láti bá wọn gbé fún ọjọ́ méje: bẹ́ẹ̀ ni a sì lọ sí ìhà Róòmù.
15 Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúró pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjọ títí wọ́n fi dé Api-fórù àti sí ilé-èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígba tí Pọ́ọ̀lù sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le.
16 Nígbà tí a sì dé Róòmù, olórí àwọn ọmọ ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀sọ́ lọ́wọ́: ṣùgbọ́n wọ́n gba Pọ́ọ̀lù láàyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń sọ́ ọ.
17 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Pọ́ọ̀lù pe àwọn olórí Júù jọ: nígbà tí wọ́n sì péjọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ara, bí ó ti se pé èmi kò se ohun kan lòdì sí àwọn ènìyàn, tàbí sí àṣà àwọn baba wa, ṣíbẹ̀ wọ́n fi mí lé àwọn ara Róòmù lọ́wọ́ ní òǹdè láti Jerúsálémù wá.
18 Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀ràn mi, wọ́n fẹ́ jọ̀wọ́ mi lọ́wọ́ lọ, nítorí tí wọn kò rí ẹ̀sùn kan tí ó tọ́ sí ikú pẹ̀lú mi.