2 Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn alàìgbédè náà ṣe fún wa: nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù.
3 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì sa ìdí ìwọ̀nwọ̀n-igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́.
4 Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú àpànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láàyè.”
5 Òun sì gbọn ẹranko náà sínu iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é.
6 Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣúbu lulẹ̀ kú lójijì: nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.
7 Ní agbégbé ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pọ́bílíù; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.
8 Ó sì ṣe, baba Pọ́bílíù dubulẹ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Pọ́ọ̀lù wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá.