9 Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónì ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá,
10 Kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì pé, ni orúkọ Jésù Kírísítì ti Násárétì, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá.
11 Èyí ni“ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’
12 Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlomìíràn; nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fifún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.”
13 Nígbà tí wọ́n sì kíyèsí ìgboyà Pétérù àti Jòhánù, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jésù gbé.
14 Nígbà tí wọ́n sì ń wo ọkùnrin náà tí a mú láradá, tí ó bá wọn dúró, wọn kò rí nǹkan wí sí i.
15 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sì ti pàṣẹ pé kí wọn jáde kúrò ní ìgbìmọ̀, wọ́n bá ara wọn gbérò.