42 Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé:“ ‘Ẹ̀yin hà mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún miní ogójì ọdún ní ijù bí, Ìwọ ilé Ísírẹ́lì?
43 Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gba ojúbọ Mólókù,àti ìràwọ̀ Ráfánì òrìṣà yín,àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ.Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Bábílónì.’
44 “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijú. Èyí tí a se gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mósè sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ tí ó ti rí.
45 Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Jóṣúà wá sí ilẹ̀-ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókó Dáfídì.
46 Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jákọ́bù.
47 Ṣùgbọ́n Sólómónì ni ó kọ́ ilé fún un,
48 “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé: