45 Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Jóṣúà wá sí ilẹ̀-ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókó Dáfídì.
46 Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jákọ́bù.
47 Ṣùgbọ́n Sólómónì ni ó kọ́ ilé fún un,
48 “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:
49 “ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,ayé ni àpòtí ìtìsẹ̀ mi.Irú ilé kínní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi?ni Olúwa wí.Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi isinmi mi?
50 Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’
51 “Ẹ̀yin ọlọ́rùn-líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yín rí: Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́!