14 Nígbà tí àwọn àpósítélì tí ó wà ní Jerúsálémù sí gbọ́ pé àwọn ara Samaríà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Pétérù Àti Jòhánù sí wọn.
15 Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́:
16 nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bá lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitíìsì wọn lórúkọ Jésù Olúwa ni.
17 Nígbà náà ni Pétérù àti Jòhánù gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.
18 Nígbà tí Símónì rí i pé nípa gbígbe ọwọ́ leni ni a ń ti ọwọ́ àwọn àpósítélì fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n,
19 ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”
20 Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run!