20 Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run!
21 Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déedé níwájú Ọlọ́run.
22 Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búrurú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dári ète ọkàn rẹ jì ọ́.
23 Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹrò ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.”
24 Nígbà náà ni Símónì dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”
25 Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, ti wọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Pétérù àti Jòhánù padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì wàásù ìyìn rere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn Samaríà.
26 Ańgẹ́lì Olúwa sì sọ fún Fílípì pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerúsálémù lọ sí Gásà.”