6 Ó sì ya ẹnu rẹ̀ ni ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rẹ̀, àti sí àgọ́ rẹ̀, àti sí àwọn tí ń gbé ọ̀run.
7 A sì fún-un láti máa bá àwọn ènìyàn-mímọ́ jagun, àti láti ṣẹ́gun wọn: a sì fi agbára fún un lórí gbogbo ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti èdè, àti orílẹ̀.
8 Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlúkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé-ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.
9 Bí ẹnikẹ́ni bá létí kí o gbọ́.
10 Ẹni tí a ti pinnu rẹ̀ fún ìgbékùn,ìgbékùn ni yóò lọ;ẹni tí a sì ti pinnu rẹ̀ fún idà,ni a ó sì fi idà pa.Nihìn-ín ni sùúrù àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn mímọ́ wà.
11 Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá; ó sì ní ìwo méjì bí Ọ̀dọ́-Àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dírágónì.
12 Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn.