8 Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlúkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé-ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.
9 Bí ẹnikẹ́ni bá létí kí o gbọ́.
10 Ẹni tí a ti pinnu rẹ̀ fún ìgbékùn,ìgbékùn ni yóò lọ;ẹni tí a sì ti pinnu rẹ̀ fún idà,ni a ó sì fi idà pa.Nihìn-ín ni sùúrù àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn mímọ́ wà.
11 Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá; ó sì ní ìwo méjì bí Ọ̀dọ́-Àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dírágónì.
12 Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn.
13 Ó sì ń ṣe ohun ìyanu ńlá, àní tí ó fi ń mú iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sì ilẹ̀ ayé níwájú àwọn ènìyàn.
14 Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fí fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà; ó ń wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti yá àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè.