Ìfihàn 20:3-9 BMY

3 Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbún náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má ba à tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé: Lẹ́yìn èyí, a kò le sàì tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

4 Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọn: mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jésù, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà àmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Kírísítì ní ẹgbẹ̀rún ọdún.

5 Àwọn òkú ìyókù kò wà láàyè mọ́ títí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò fi pé. Èyí ni àjíǹde èkíní.

6 Olúkúlùkù àti mímọ́ ni ẹni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkíní náà: lórí àwọn wọ̀nyí ikú eekejì kò ní agbára, ṣùgbọ́n wọn ó jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kírísítì, wọn ó sì máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọdún.

7 Nígbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá sì pé, a ó tú Sàtánì sílẹ̀ kúrò nínú túbú rẹ̀.

8 Yóò sì jáde lọ láti máa tan àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé jẹ, Gógù àti Mágógú, láti gbá wọn jọ sí ogun: àwọn tí iyè wọn dàbí iyanrìn òkun.

9 Wọ́n sì gòkè lọ la ibú ayé já, wọ́n sì yí ibùdó àwọn ènìyàn mímọ́ ká àti ìlú àyànfẹ́ náà: iná sì ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó sì jó wọn run.