4 “Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín,gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́.Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe,ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo.
5 Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli ti hu ìwà aiṣododo sí i,ẹ kò sì yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ̀ mọ́,nítorí àbùkù yín;ẹ̀yin ìran ọlọ̀tẹ̀ ati ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí.
6 Ṣé irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún OLUWA nìyí,ẹ̀yin ìran òmùgọ̀ ati aláìnírònú ẹ̀dá wọnyi?Ṣebí òun ni baba yín, tí ó da yín,Tí ó da yín tán, tí ó sì fi ìdí yín múlẹ̀.
7 “Ẹ ranti ìgbà àtijọ́,ẹ ṣe akiyesi ọpọlọpọ ọdún tí ó ti kọjá.Ẹ bèèrè lọ́wọ́ baba yín, yóo fihàn yín,Ẹ bi àwọn àgbààgbà yín,wọn yóo sì sọ fun yín.
8 Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè,ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé,gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli.
9 Nítorí pé ìpín OLUWA ni àwọn eniyan rẹ̀,ó yan àwọn ọmọ Jakọbu ní ohun ìní fún ara rẹ̀.
10 “Ninu aṣálẹ̀ ni ó ti rí wọn,níbi tí kò sí igi tabi koríko, àfi kìkì yanrìn.Ó yí wọn ká, ó sì ń tọ́jú wọn,Ó sì dáàbò bò wọ́n bí ẹyin ojú rẹ̀.