26 Nítorí pé ninu gbogbo ẹ̀dá alààyè, ta ni ó tíì gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun alààyè rí láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ ọ yìí, tí ó sì wà láàyè?
27 Ìwọ Mose, súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yóo sọ, kí o wá sọ fún wa, a óo sì ṣe é.’
28 “OLUWA gbọ́ ọ̀rọ̀ yín nígbà tí ẹ̀ ń bá mi sọ̀rọ̀, ó sì wí fún mi pé, ‘Mo gbọ́ ohun tí àwọn eniyan wọnyi bá ọ sọ; gbogbo ohun tí wọ́n sọ pátá ni ó dára.
29 Yóo ti dára tó, bí wọ́n bá ní irú ẹ̀mí yìí nígbà gbogbo, kí wọ́n bẹ̀rù mi, kí wọ́n sì pa gbogbo òfin mi mọ́, kí ó lè dára fún wọn, ati fún àwọn ọmọ wọn títí lae.
30 Lọ sọ fún wọn pé, kí wọ́n pada sinu àgọ́ wọn.
31 Ṣugbọn ìwọ dúró tì mí níhìn-ín, n óo sì sọ gbogbo òfin ati ìlànà ati ìdájọ́ tí o óo kọ́ wọn, kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́, ní ilẹ̀ tí n óo fún wọn.’
32 “Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yín pa láṣẹ fun yín; ẹ kò gbọdọ̀ ṣe àìgbọràn ninu ohunkohun.