1 Àwọn òwe tí Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli pa,
2 kí àwọn eniyan lè ní ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́,kí òye ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lè yé wọn,
3 láti gba ẹ̀kọ́, tí yóo kọ́ni lọ́gbọ́n,òdodo, ẹ̀tọ́ ati àìṣojúṣàájú,
4 láti kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́gbọ́n,kí á sì fi ìmọ̀ ati làákàyè fún ọ̀dọ́,
5 kí ọlọ́gbọ́n lè gbọ́, kí ó sì fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀,kí ẹni tí ó ní òye lè ní ìmọ̀ pẹlu.
6 Láti lè mọ òwe ati àkàwé ọ̀rọ̀,ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ati àdììtú ọ̀rọ̀.