1 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ baba yín,ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ lè ní ìmọ̀,
2 nítorí pé mo fun yín ní ìlànà rere,ẹ má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi.
3 Nígbà tí mo wà ní ọmọde lọ́dọ̀ baba mi,tí mo jẹ́ ẹni ìkẹ́, ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi,
4 baba mi kọ́ mi, ó ní,“Fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn,pa òfin mi mọ́, kí o lè wà láàyè.
5 Jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí o sì ní ìmọ̀.Má gbàgbé, má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu.
6 Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóo pa ọ́ mọ́,fẹ́ràn rẹ̀, yóo sì dáàbò bò ọ́.
7 Bí o bá fẹ́ gbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́gbọ́n,ohun yòówù tí o lè tún ní,ọgbọ́n ló jù, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
8 Gbé ọgbọ́n lárugẹ, yóo sì gbé ọ ga,yóo bu ọlá fún ọ, bí o bá gbà á mọ́ra.
9 Yóo fi nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà bò ọ́ lórí,yóo sì dé ọ ní adé dáradára.”
10 Gbọ́, ọmọ mi, gba ẹ̀kọ́ mi,kí ẹ̀mí rẹ lè gùn.
11 Mo ti kọ́ ọ ní ọgbọ́n,mo sì ti fẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà òtítọ́.
12 Nígbà tí o bá ń rìn, o kò ní rí ìdínà,nígbà tí o bá ń sáré, o kò ní fi ẹsẹ̀ kọ.
13 Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin,má jẹ́ kí ó bọ́,pa á mọ́, nítorí òun ni ìyè rẹ.
14 Má ṣe gba ọ̀nà ẹni ibi,má sì ṣe rin ọ̀nà eniyan burúkú.
15 Yẹra fún un,má tilẹ̀ kọjú sí ọ̀nà ibẹ̀,ṣugbọn gba ibòmíràn, kí o máa bá tìrẹ lọ.
16 Nítorí wọn kì í lè é sùn, bí wọn kò bá tíì ṣe ibi,oorun kì í kùn wọ́n, tí wọn kò bá tíì fa ìṣubú eniyan.
17 Ìkà ṣíṣe ni oúnjẹ wọn,ìwà ipá sì ni ọtí waini wọn.
18 Ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́,tí ń mọ́lẹ̀ sí i láti ìdájí títí tí ilẹ̀ yóo fi mọ́ kedere.
19 Ọ̀nà eniyan burúkú dàbí òkùnkùn biribiri,wọn kò mọ ohun tí wọn yóo dìgbò lù.
20 Ọmọ mi, fetí sí ọ̀rọ̀ mi,tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun tí mò ń sọ.
21 Má jẹ́ kí wọn rú ọ lójú,fi wọ́n sọ́kàn.
22 Nítorí pé ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó rí wọn,ati ìwòsàn fún gbogbo ẹran ara wọn.
23 Ṣọ́ra pẹlu èrò ọkàn rẹ,nítorí èrò ọkàn ni orísun ìyè.
24 Má lọ́wọ́ ninu ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ,sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ àgàbàgebè.
25 Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán,kí o sì kọjú sí ibi tí ò ń lọ tààrà.
26 Kíyèsí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ,gbogbo ọ̀nà rẹ yóo sì là.
27 Má ṣe yà sí ọ̀tún tabi sí òsì,yipada kúrò ninu ibi.