1 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀,ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè.
2 Lẹ́nu ọlọ́gbọ́n ni ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ti ń jáde,ṣugbọn òmùgọ̀ a máa sọ̀rọ̀ agọ̀.
3 Ojú OLUWA wà níbi gbogbo,ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere.
4 Ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́ sọ dàbí igi ìyè,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn a máa bani lọ́kàn jẹ́.
5 Òmùgọ̀ ọmọ á kẹ́gàn ìtọ́sọ́nà baba rẹ̀,ṣugbọn ọmọ tí ó gbọ́ ìkìlọ̀, ọlọ́gbọ́n ni.
6 Ilé olódodo kún fún ọpọlọpọ ìṣúra,ṣugbọn kìkì ìdààmú ni àkójọ èrè eniyan burúkú.
7 Ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa tan ìmọ̀ kálẹ̀,ṣugbọn ti òmùgọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.
8 Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú lójú OLUWA,ṣugbọn adura olódodo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.
9 OLUWA kórìíra ìwà àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn ó fẹ́ràn àwọn tí ń hùwà òdodo.
10 Ìbáwí pupọ ń bẹ fún ẹni tí ó yapa kúrò ní ọ̀nà rere,ẹni tí ó bá kórìíra ìbáwí yóo kú.
11 Isà òkú ati ìparun kò pamọ́ lójú OLUWA,mélòó-mélòó ni ọkàn eniyan.
12 Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí,kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n.
13 Inú dídùn a máa múni dárayá,ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì.
14 Ẹni tí ó ní òye a máa wá ìmọ̀,ṣugbọn agọ̀ ni oúnjẹ òmùgọ̀.
15 Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú,ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn.
16 Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA,ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ.
17 Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́,sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.
18 Onínúfùfù a máa rú ìjà sókè,ṣugbọn onínútútù a máa pẹ̀tù sí ibinu.
19 Ẹ̀gún kún bo ọ̀nà ọ̀lẹ,ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí òpópó tí ń dán.
20 Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn,ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ níí kẹ́gàn ìyá rẹ̀.
21 Ayọ̀ ni ìwà òmùgọ̀ jẹ́ fún aláìgbọ́n,ṣugbọn ẹni tí ó ní òye a máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.
22 Àìsí ìmọ̀ràn a máa mú kí ètò dàrú,ṣugbọn ọpọlọpọ ìmọ̀ràn a máa mú kí ó yọrí sí rere.
23 Ìdáhùn kíkún a máa fúnni láyọ̀,kí ọ̀rọ̀ bọ́ sí àsìkò dára lọpọlọpọ!
24 Ọ̀nà ọlọ́gbọ́n lọ tààrà sinu ìyè,kí ó má baà bọ́ sinu isà òkú.
25 OLUWA a máa wó ilé agbéraga,ṣugbọn ó ṣe àmójútó ààlà opó.
26 Ohun ìríra ni èrò ọkàn ẹni ibi lójú OLUWA,ṣugbọn ọrọ̀ àwọn ẹni mímọ́ jẹ́ dídùn inú rẹ̀.
27 Àwọn tí ń ṣojúkòkòrò èrè àìtọ́ ń kó ìyọnu bá ilé wọn,ṣugbọn àwọn tí wọn kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóo yè.
28 Olódodo a máa ronú kí ó tó fèsì ọ̀rọ̀,ṣugbọn ọ̀rọ̀ burúkú níí máa jáde lẹ́nu àwọn eniyan burúkú.
29 OLUWA jìnnà sí eniyan burúkú,ṣugbọn a máa gbọ́ adura olódodo.
30 Ọ̀yàyà a máa mú inú dùn,ìròyìn ayọ̀ a sì máa mú ara yá.
31 Ẹni tó gbọ́ ìbáwí rereyóo wà láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n.
32 Ẹni tí kò náání ìbáwí tàbùkù ara rẹ̀,ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ràn yóo ní òye.
33 Ìbẹ̀rù OLUWA níí kọ́ni lọ́gbọ́n,ìwà ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.