Ìwé Òwe 21 BM

1 Orísun omi ni ọkàn ọba lọ́wọ́ OLUWA,ibi tí ó bá wu Oluwa ni ó ń darí rẹ̀ sí.

2 Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó dára lójú ara rẹ̀,ṣugbọn ọkàn ni OLUWA ń wò.

3 Kí eniyan ṣe òdodo ati ẹ̀tọ́,sàn ju ẹbọ lọ lójú OLUWA.

4 Bíi fìtílà ẹni ibi ni gbígbé ojú gangan ati ìgbéraga,ẹ̀ṣẹ̀ sì ni wọ́n.

5 Dájúdájú èrò ẹni tí ó ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn yóo yọrí sí ọ̀pọ̀,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń kánjú jù kò ní ní ànító.

6 Fífi èké kó ìṣúra jọdàbí lílé ìkùukùu, ó sì jẹ́ tàkúté ikú.

7 Ìwà ipá àwọn ẹni ibi ni yóo gbá wọn dànù,nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe òtítọ́.

8 Ọ̀nà ẹlẹ́bi kì í gún,ṣugbọn ìrìn aláìlẹ́bi a máa tọ́.

9 Ó sàn láti máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà,ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ.

10 Ibi ni ọkàn eniyan burúkú máa ń fẹ́,àwọn aládùúgbò rẹ̀ kì í sìí rí ojurere rẹ̀.

11 Ìjìyà ẹlẹ́yà a máa mú kí òpè gbọ́n,tí a bá ń kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo ní ìmọ̀ sí i.

12 Olódodo ṣàkíyèsí ilé eniyan burúkú,eniyan burúkú sì bọ́ sinu ìparun.

13 Ẹni tí ó kọ etí dídi sí igbe talaka,òun náà yóo kígbe, ṣugbọn kò ní rí ẹni dá a lóhùn.

14 Ẹ̀bùn tí a fúnni ní kọ̀rọ̀ a máa paná ibinu,àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí a tì bọ abẹ́ aṣọ a máa paná ìjà.

15 Tí a bá ṣe ìdájọ́ òtítọ́, inú olódodo a dùn,ṣugbọn ìfòyà ni fún àwọn aṣebi.

16 Ẹni tí ó sá kúrò lọ́nà òyeyóo sinmi láàrin àwọn òkú.

17 Ẹni tí ó fẹ́ràn fàájì yóo di talaka,ẹni tí ó fẹ́ràn ọtí waini ati òróró kò ní lówó lọ́wọ́.

18 Eniyan burúkú ni yóo forí gba ibitíì bá dé bá olódodo.Alaiṣootọ ni yóo fara gba ìyà tí ó tọ́ sí olóòótọ́ inú.

19 Ó sàn láti máa gbé ààrin aṣálẹ̀,ju kí eniyan máa bá oníjà ati oníkanra obinrin gbé lọ.

20 Ní ilé ọlọ́gbọ́n ni à á tí ń bá nǹkan olówó iyebíye,ṣugbọn òmùgọ̀ a máa ba tirẹ̀ jẹ́.

21 Ẹni tí ń lépa òdodo ati àánúyóo rí ìyè, òdodo, ati iyì.

22 Ọlọ́gbọ́n a máa gba ìlú àwọn alágbáraa sì wó ibi ààbò tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé lulẹ̀.

23 Ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́pa ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu ìyọnu.

24 “Oníyẹ̀yẹ́” ni orúkọ ẹni tí ń gbéraga,tí ó sì ń ṣe mo tó báyìí-dà báyìí.

25 Ìrònú ohun tí ọ̀lẹ fẹ́ ni yóo pa á,nítorí ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́.

26 Eniyan burúkú a máa ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ìgbà,ṣugbọn olódodo ń fúnni láìdáwọ́dúró.

27 Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú,pàápàá tí ó bá mú un wá pẹlu èrò ibi.

28 Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́rìí èké yóo di asán,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹni tí ó fetí sílẹ̀ ni a óo gbàgbọ́.

-5-

29 Eniyan burúkú a máa lo ògbójú,ṣugbọn olóòótọ́ máa ń yẹ ọ̀nà ara rẹ̀ wò.

30 Kò sí ọgbọ́n, tabi òye, tabi ìmọ̀,tí ó lè dojú kọ OLUWA kí ó mókè.

31 Eniyan a máa tọ́jú ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun,ṣugbọn OLUWA ló ni ìṣẹ́gun.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31