Ìwé Òwe 31 BM

Ìmọ̀ràn fún Ọba

1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Lemueli, ọba Masa, tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ:

2 Ìwọ ni ọmọ mi, ọmọ bíbí inú mi,ìwọ ni ọmọ tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́ bí.

3 Má ṣe lo agbára rẹ lórí obinrin,má fi ọ̀nà rẹ lé àwọn tí wọn ń pa ọba run lọ́wọ́.

4 Gbọ́, ìwọ Lemueli,ọba kò gbọdọ̀ máa mu ọtí,àwọn aláṣẹ kò sì gbọdọ̀ máa wá ọtí líle.

5 Kí wọn má baà mu ún tán, kí wọn gbàgbé òfin,kí wọn sì yí ìdájọ́ ẹni tí ojú ń pọ́n po.

6 Fún ẹni tí ń ṣègbé lọ ní ọtí mu,fún àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ ní ọtí líle,

7 jẹ́ kí wọn mu ún, kí wọn gbàgbé òṣì wọn,kí wọn má sì ranti ìnira wọn mọ́.

8 Gba ẹjọ́ àwọn tí kò ní ẹnu ọ̀rọ̀ rò,ati ti àwọn tí a sọ di aláìní.

9 Má dákẹ́, kí o ṣe ìdájọ́ òdodo,bá talaka ati aláìní gba ẹ̀tọ́ wọn.

Iyawo tí Ó Ní Ìwà Rere

10 Ta ló lè rí iyawo tí ó ní ìwà rere fẹ́?Ó ṣọ̀wọ́n ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ.

11 Ọkọ rẹ̀ yóo fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé e,kò sì ní ṣaláì ní ohunkohun.

12 Rere ni obinrin náà máa ń ṣe fún unkò ní ṣe é níbi, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

13 A máa lọ wá irun aguntan ati òwú ìhunṣọ,a sì máa fi tayọ̀tayọ̀ hun aṣọ.

14 Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò,tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré.

15 Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀,ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀.

16 Bí ó bá rí ilẹ̀ oko, a yẹ̀ ẹ́ wò, a sì rà á,a sì fi èrè iṣẹ́ rẹ̀ gbin ọgbà àjàrà.

17 A fi agbára fún ọ̀já mọ́nú,a sì tẹpá mọ́ṣẹ́.

18 A máa mójútó ọjà tí ó ń tà,fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú lóru.

19 Ó fi ọwọ́ lé kẹ̀kẹ́ òwú,ó sì ń ran òwú.

20 Ó lawọ́ sí àwọn talaka,a sì máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́.

21 Kì í bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nígbà òtútù,nítorí gbogbo wọn ni ó ti bá hun aṣọ tí ó móoru.

22 A máa hun aṣọ ọlọ́nà a sì fi bo ibùsùn rẹ̀,òun náà á wọ aṣọ funfun dáradára ati ti elése àlùkò.

23 Wọ́n dá ọkọ rẹ̀ mọ̀ lẹ́nu ibodè,nígbà tí ó bá jókòó pẹlu àwọn àgbààgbà ìlú.

24 A máa hun aṣọ funfun, a sì tà wọ́n,a máa ta ọ̀já ìgbànú fún àwọn oníṣòwò.

25 Agbára ati ọlá ni ó fi ń bora bí aṣọ,ó sì ní ìrètí ayọ̀ nípa ọjọ́ iwájú.

26 Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní ń jáde láti ẹnu rẹ̀,a sì máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ àánú.

27 A máa ṣe ìtọ́jú ìdílé rẹ̀ dáradára,kì í sì í hùwà ọ̀lẹ.

28 Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa pè é ní ẹni ibukun,ọkọ rẹ̀ pẹlu a sì máa yìn ín pé,

29 “Ọpọlọpọ obinrin ni wọ́n ti ṣe ribiribi,ṣugbọn ìwọ ta gbogbo wọn yọ.”

30 Ẹ̀tàn ni ojú dáradára, asán sì ni ẹwà,obinrin tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni ó yẹ kí á yìn.

31 Fún un ninu èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,jẹ́ kí wọn máa yìn ín lẹ́nu ibodè nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31