1 Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀,ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni.
2 Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi.
3 Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀,ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu.
4 Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀,ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun.
5 Èrò ọkàn olódodo dára,ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.
6 Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là.
7 A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun,ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin.
8 À máa ń yin eniyan gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe gbọ́n tó,ṣugbọn ọlọ́kàn àgàbàgebè yóo di ẹni ẹ̀gàn.
9 Mẹ̀kúnnù tí ó ní iṣẹ́, tí ó tún gba ọmọ-ọ̀dọ̀ó sàn ju ẹni tí ó ń ṣe bí eniyan pataki, ṣugbọn tí kò rí oúnjẹ jẹ lọ.
10 Olódodo a máa ka ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sí,ṣugbọn eniyan burúkú rorò sí tirẹ̀.
11 Ẹni tí ó bá ń dáko yóo ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lo àkókò rẹ̀ lórí ohun tí kò lérè, kò lọ́gbọ́n lórí.
12 Ilé ìṣọ́ àwọn eniyan burúkú yóo di òkítì àlàpà,ṣugbọn gbòǹgbò eniyan rere a máa fìdí múlẹ̀ sí i.
13 Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan burúkú a máa mú un bíi tàkúté,ṣugbọn olódodo a máa bọ́ ninu ìyọnu.
14 Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa mú ìtẹ́lọ́rùn bá a,a sì máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
15 Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn.
16 Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí.
17 Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo,ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa.
18 Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn.
19 Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayéṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni.
20 Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi,ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀.
21 Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo,ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu.
22 OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́,ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́.
23 Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́,ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn.
24 Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí,ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá.
25 Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn.
26 Olódodo a máa yipada kúrò ninu ibi,ṣugbọn ìwà ẹni ibi a máa mú un ṣìnà.
27 Ọwọ́ ọ̀lẹ kò lè tẹ ohun tí ó ń lé,ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀.
28 Ní ọ̀nà òdodo ni ìyè wà,kò sí ikú ní ojú ọ̀nà rẹ̀.