Ìwé Òwe 18 BM

1 Onímọ-tara-ẹni-nìkan ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀,láti tako ìdájọ́ òtítọ́.

2 Òmùgọ̀ kò ní inú dídùn sí ìmọ̀,àfi kí ó ṣá máa sọ èrò ọkàn rẹ̀.

3 Nígbà tí ìwà burúkú bá dé, ẹ̀gàn yóo dé,bí àbùkù bá wọlé ìtìjú yóo tẹ̀lé e.

4 Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan dàbí odò jíjìn,orísun ọgbọ́n dàbí omi odò tí ń tú jáde.

5 Kò dára kí á ṣe ojuṣaaju sí eniyan burúkú,tabi kí á dá olódodo ní ẹjọ́ ẹ̀bi.

6 Ẹnu òmùgọ̀ a máa dá ìjà sílẹ̀,ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa bá a wá pàṣán.

7 Ẹnu òmùgọ̀ ni yóo tì í sinu ìparun,ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ni yóo sì ṣe tàkúté mú un.

8 Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùn,a máa wọni lára ṣinṣin.

9 Ẹni tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀,ẹgbẹ́ ni òun ati ẹni tí ń ba nǹkan jẹ́.

10 Orúkọ OLUWA jẹ́ ilé-ìṣọ́ tí ó lágbára,olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì yè.

11 Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi wọn,lójú wọn, ó dàbí odi ńlá tí ń dáàbò bò wọ́n.

12 Ìgbéraga níí ṣáájú ìparun,ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.

13 Ìwà òmùgọ̀ ni, ìtìjú sì ni, kí eniyan fèsì sí ọ̀rọ̀ kí ó tó gbọ́ ìdí rẹ̀.

14 Eniyan lè farada àìsàn,ṣugbọn ta ló lè farada ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn?

15 Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa fẹ́ ìmọ̀,etí ni ọlọ́gbọ́n fi wá a kiri.

16 Ẹ̀bùn a máa ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn,a sì mú un dé iwájú ẹni gíga.

17 Ẹni tí ó bá kọ́kọ́ rojọ́ níí dàbí ẹni tí ó jàre,títí tí ẹnìkejì yóo fi bi í ní ìbéèrè,

18 Gègé ṣíṣẹ́ a máa yanjú ọ̀rọ̀a sì parí gbolohun asọ̀ láàrin àwọn alágbára.

19 Ọkàn arakunrin tí eniyan bá ṣẹ̀ a máa le bí ìlú olódi,àríyànjiyàn sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ilé ìṣọ́.

20 Eniyan lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu wá oúnjẹ fún ara rẹ̀,a lè jẹ oúnjẹ tí a bá fi ọ̀rọ̀ ẹnu wání àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù.

21 Ahọ́n lágbára láti pani ati láti lani,ẹni tí ó bá fẹ́ràn rẹ̀ yóo jèrè rẹ̀.

22 Ẹni tí ó bá rí aya fẹ́ rí ohun rere, ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA.

23 Ẹ̀bẹ̀ ni talaka bẹ̀,ṣugbọn ọlọ́rọ̀ á dáhùn tìkanra-tìkanra.

24 Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà, ọ̀rẹ́ àfẹnujẹ́ ni wọ́n,ṣugbọn ọ̀rẹ́ mìíràn wà tí ó fi ara mọ́ni ju ọmọ ìyá ẹni lọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31