Ìwé Òwe 8 BM

Yíyin Ọgbọ́n

1 Ọgbọ́n ń pe eniyan,òye ń pariwo.

2 Ó dúró ní ibi tí ó ga lẹ́bàá ọ̀nà,ati ní ojú ọ̀nà tóóró,

3 ó ń kígbe lóhùn rara lẹ́nu ibodè àtiwọ ìlú,ó ń ké ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pẹlu,ó ń wí pé:

4 “Ẹ̀yin eniyan ni mò ń pè,gbogbo ọmọ eniyan ni mò ń ké sí.

5 Ẹ̀yin òpè, ẹ kọ́ ọgbọ́n,ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ fetí sí òye.

6 Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ pataki ni mo fẹ́ sọ.Ohun tí ó tọ́ ni n óo sì fi ẹnu mi sọ.

7 Ọ̀rọ̀ òtítọ́ ni yóo ti ẹnu mi jáde,nítorí mo kórìíra ọ̀rọ̀ burúkú.

8 Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi,kò sí ìtànjẹ tabi ọ̀rọ̀ àrékérekè ninu wọn.

9 Gbogbo ọ̀rọ̀ náà tọ́ lójú ẹni tí ó mòye,wọn kò sì ní àbùkù lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀.

10 Gba ẹ̀kọ́ mi dípò fadaka,ati ìmọ̀ dípò ojúlówó wúrà,

11 nítorí ọgbọ́n níye lórí ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ,kò sí ohun tí o fẹ́, tí a lè fi wé e.

12 Èmi, ọgbọ́n, òye ni mò ń bá gbélé,mo ṣe àwárí ìmọ̀ ati làákàyè.

13 Ẹni tó bá bẹ̀rù OLUWA, yóo kórìíra ibi,mo kórìíra ìwà ìgbéraga, ọ̀nà ibi ati ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.

14 Èmi ni mo ní ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n tí ó yè kooro,mo sì ní òye ati agbára.

15 Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọba fi ń ṣe ìjọba,tí àwọn alákòóso sì ń pàṣẹ òdodo.

16 Nípasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣe àkóso,gbogbo àwọn ọlọ́lá sì ń ṣe àkóso ayé.

17 Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi,àwọn tí wọ́n bá fi tọkàntọkàn wá mi yóo sì rí mi.

18 Ọrọ̀ ati iyì wà níkàáwọ́ mi,ọrọ̀ tíí tọ́jọ́, ati ibukun.

19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ,àyọrísí mi sì dára ju ojúlówó fadaka lọ.

20 Ọ̀nà òdodo ni èmi ń rìn,ojú ọ̀nà tí ó tọ́ ni mò ń tọ̀.

21 Èmi a máa fún àwọn tí wọ́n fẹ́ mi ní ọrọ̀,n óo máa mú kí ìṣúra wọn kún.

22 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi,kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀.

23 Láti ayébáyé ni a ti yàn mí,láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá.

24 Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà,nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi.

25 Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn,kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà.

26 Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko,kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀.

27 Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó dá ojú ọ̀run sí ààyè rẹ̀,tí ó ṣe àmì bìrìkìtì sórí ibú,ní ibi tí ó dàbí ẹni pé ilẹ̀ ati ọ̀run ti pàdé,

28 nígbà tí ó ṣe awọsanma lọ́jọ̀,tí ó fi ìpìlẹ̀ orísun omi sọ ilẹ̀,

29 nígbà tí ó pààlà sí ibi tí òkun gbọdọ̀ kọjá,kí omi má baà kọjá ààyè rẹ̀.Nígbà tí ó sàmì sí ibi tí ìpìlẹ̀ ayé wà,

30 èmi ni oníṣẹ́ ọnà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀,Inú mi a máa dùn lojoojumọ,èmi a sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo.

31 Mo láyọ̀ ninu ayé tí àwọn ẹ̀dá alààyè ń gbé,inú mi sì ń dùn sí àwọn ọmọ eniyan.

32 “Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi,ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà mi.

33 Ẹ gbọ́ ìtọ́ni, kí ẹ sì kọ́gbọ́n,ẹ má sì ṣe àìnáání rẹ̀.

34 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbọ́ tèmi,tí ó ń ṣọ́nà lojoojumọ ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá mi,tí ó dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé mi.

35 Ẹni tí ó rí mi, rí ìyè,ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,

36 ṣugbọn ẹni tí kò bá rí mi, ó pa ara rẹ̀ lára,gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi, ikú ni wọ́n fẹ́ràn.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31