Ìwé Òwe 19 BM

1 Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú,ó sàn ju òmùgọ̀ eniyan, tí ó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ.

2 Kò dára kí eniyan wà láìní ìmọ̀,ẹni bá ń kánjú rìn jù a máa ṣìnà.

3 Nígbà tí ìwà òmùgọ̀ bá kó ìparun bá a,ọkàn rẹ̀ a máa bá OLUWA bínú.

4 Ọrọ̀ a máa mú kí eniyan ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́ titun,ṣugbọn àwọn ọ̀rẹ́ talaka a máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

5 Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kò ní bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀san ibi.

6 Ọ̀pọ̀ eniyan níí máa ń wá ojurere ẹni tó lawọ́,gbogbo eniyan sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn.

7 Gbogbo àwọn arakunrin talaka ni wọ́n kórìíra rẹ̀,kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jìnnà sí i!Ó fọ̀rọ̀ ẹnu fà wọ́n títí, sibẹ wọn kò súnmọ́ ọn.

8 Ẹni tí ó ní ọgbọ́n fẹ́ràn ara rẹ̀,ẹni tí ó bá sì ní òye, yóo ṣe rere.

9 Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,ẹni tí ó ń pa irọ́ yóo parun.

10 Ìgbádùn kò yẹ òmùgọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí ẹrú jọba lórí àwọn ìjòyè.

11 Ọgbọ́n kì í jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yára bínú,ògo rẹ̀ sì níláti fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá.

12 Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun,ṣugbọn ojurere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko tútù.

13 Òmùgọ̀ ọmọ lè kó ìparun bá baba rẹ̀,iyawo oníjà dàbí omi òjò tí ń kán tó, tó, tó, láì dáwọ́ dúró.

14 A máa ń jogún ilé ati ọrọ̀ lọ́wọ́ baba ẹni,ṣugbọn OLUWA níí fúnni ní aya rere.

15 Ìwà ọ̀lẹ a máa múni sùn fọnfọn,ebi níí sìí pa alápá-má-ṣiṣẹ́.

16 Ẹni tí ó bá pa òfin mọ́, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó pamọ́,ẹni tí ó kọ ọ̀nà Ọlọrun sílẹ̀ yóo kú.

17 Ẹni tí ó ṣe ojurere fún àwọn talaka, OLUWA ni ó ṣe é fún,OLUWA yóo sì san ẹ̀san rẹ̀ fún un.

18 Bá ọmọ rẹ wí nígbà tí ó sì lè gbọ́ ìbáwí,má sì ṣe wá ìparun rẹ̀.

19 Onínúfùfù yóo jìyà inúfùfù rẹ̀,bí o bá gbà á sílẹ̀ lónìí, o níláti tún gbà á sílẹ̀ lọ́la.

20 Gbọ́ ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́,kí o lè rí ọgbọ́n lò lẹ́yìn ọ̀la.

21 Ọpọlọpọ ni èrò tí ó wà lọ́kàn ọmọ eniyan,ṣugbọn ìfẹ́ OLUWA ni àṣẹ.

22 Ohun tí ayé ń fẹ́ lára eniyan ni òtítọ́ inú,talaka sì sàn ju òpùrọ́ lọ.

23 Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú ìyè wá,ẹni tí ó ní i yóo ní ìfọ̀kànbalẹ̀,ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí i.

24 Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ,ṣugbọn kò lè bu oúnjẹ sí ẹnu ara rẹ̀.

25 Na pẹ̀gànpẹ̀gàn eniyan, òpè yóo sì kọ́gbọ́n.Bá olóye wí, yóo sì ní ìmọ̀ sí i.

26 Ẹni tí ó bá kó baba rẹ̀ nílé, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde,ọmọ tíí fa ìtìjú ati àbùkù báni ni.

27 Ọmọ mi, bí o bá kọ etí dídi sí ẹ̀kọ́,o óo ṣìnà kúrò ninu ìmọ̀.

28 Ẹlẹ́rìí èké a máa kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́,eniyan burúkú a máa jẹ ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni jẹun.

29 Ìjìyà ti wà nílẹ̀ fún ẹlẹ́yà,a sì ti tọ́jú pàṣán sílẹ̀ fún ẹ̀yìn òmùgọ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31