Ìwé Òwe 27 BM

1 Má lérí nípa ọ̀la,nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

2 Ẹlòmíràn ni kí o jẹ́ kí ó yìn ọ́, má yin ara rẹ,jẹ́ kí ó ti ẹnu ẹlòmíràn jáde,kí ó má jẹ́ láti ẹnu ìwọ alára.

3 Òkúta wúwo, yanrìn sì tẹ̀wọ̀n,ṣugbọn ìmúnibínú aṣiwèrè wúwo lọ́kàn ẹni ju mejeeji lọ.

4 Ìkà ni ibinu, ìrúnú sì burú lọpọlọpọ,ṣugbọn, ta ló lè dúró níwájú owú jíjẹ?

5 Ìbáwí ní gbangba sàn ju ìfẹ́ kọ̀rọ̀ lọ.

6 Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ ẹni lè dunni bí ọgbẹ́;ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìfẹnukonu ọ̀tá.

7 Ẹni tí ó yó lè wo oyin ní àwòmọ́jú,ṣugbọn bí nǹkan tilẹ̀ korò a máa dùn,lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.

8 Ẹni tí ó ṣìnà ilé rẹ̀,dàbí ẹyẹ tí ó ṣìnà ìtẹ́ rẹ̀.

9 Òróró ati turari a máa mú inú dùn,ṣugbọn láti inú ìmọ̀ràn òtítọ́ ni adùn ọ̀rẹ́ ti ń wá.

10 Má pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì ati àwọn ọ̀rẹ́ baba rẹ;má sì lọ sí ilé arakunrin rẹ ní ọjọ́ ìṣòro rẹ.Nítorí pé aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni sàn ju arakunrin tí ó jìnnà sí ni lọ.

11 Ọmọ mi, gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn,kí n lè rí ẹnu dá àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi lóhùn.

12 Amòye eniyan rí ewu, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́,ṣugbọn òpè kọjá lọ láàrin rẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.

13 Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,kí o sì gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ rẹ̀,tí ó bá ṣe onídùúró fún àjèjì obinrin.

14 Ẹni tí ó jí ní kutukutu òwúrọ̀,tí ó ń fi ariwo kí aládùúgbò rẹ̀,kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń ṣépè.

15 Iyawo oníjà dàbí omi òjò,tí ń kán tó! Tó! Tó! Láì dáwọ́ dúró;

16 ẹni tí bá ń gbìyànjú láti dá irú obinrin bẹ́ẹ̀ lẹ́kundàbí ẹni tí ń gbìyànjú láti dá afẹ́fẹ́ dúró,tabi ẹni tó fẹ́ fi ọwọ́ mú epo.

17 Bí irin ti ń pọ́n irin,bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀.

18 Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ,ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀.

19 Bí omi tíí fi bí ojú ẹni ti rí han ni,bẹ́ẹ̀ ni ọkàn eniyan ń fi irú ẹni tí eniyan jẹ́ hàn.

20 Ìparun ati isà òkú kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn,bẹ́ẹ̀ náà ni ojú eniyan, kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.

21 Iná ni a fi ń dán wúrà ati fadaka wò,ìyìn ni a fi ń dán eniyan wò.

22 Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó,kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà,ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.

23 Rí i dájú pé o mọ̀ bí agbo ẹran rẹ ti rí,sì máa tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran rẹ dáradára;

24 nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí,kí adé pẹ́ lórí kì í ṣe láti ìrandíran.

25 Lẹ́yìn tí a bá gé koríko, tí koríko tútù mìíràn sì hù,tí a bá kó koríko tí a gé lára àwọn òkè wálé,

26 o óo rí irun aguntan fi hun aṣọ,o óo sì lè fi owó tí o bá pa lórí àwọn ewúrẹ́ rẹ ra ilẹ̀.

27 O óo rí omi wàrà ewúrẹ́ rẹ fún, tí o óo máa rí mu,ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ pẹlu.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31