Ìwé Òwe 24 BM

1 Má ṣe ìlara àwọn ẹni ibi,má sì ṣe bá wọn kẹ́gbẹ́,

2 nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ìparun,ẹnu wọn sì ń sọ̀rọ̀ ìkà.

-20-

3 Ọgbọ́n ni a fi ń kọ́lé,òye ni a fi ń fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

4 Pẹlu ìmọ̀ ni eniyan fi í kóoniruuru nǹkan ìní dáradáraolówó iyebíyekún àwọn yàrá rẹ̀

-21-

5 Ọlọ́gbọ́n lágbára ju akọni lọ,ẹni tí ó ní ìmọ̀ sì ju alágbára lọ.

6 Nítorí nípa ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n, o lè jagun,ọpọlọpọ ìmọ̀ràn níí sìí mú ìṣẹ́gun wà.

-22-

7 Ọgbọ́n ga jù fún òmùgọ̀,kì í lè lanu sọ̀rọ̀ láwùjọ.

-23-

8 Ẹni tí ń pète àtiṣe ibini a óo máa pè ní oníṣẹ́ ibi.

9 Ẹ̀ṣẹ̀ ni ète òmùgọ̀,ẹni ìríra sì ni pẹ̀gànpẹ̀gàn.

24

10 Bí o bá kùnà lọ́jọ́ ìpọ́njú,a jẹ́ pé agbára rẹ kò tó.

-25-

11 Gba àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ pa sílẹ̀,fa àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n,lọ sọ́dọ̀ àwọn apànìyàn pada.

12 Bí ẹ bá sọ pé ẹ kò mọ nǹkan nípa rẹ̀,ṣé ẹni tí ó mọ èrò ọkàn kò rí i?Ṣé ẹni tí ń pa ẹ̀mí rẹ mọ́ kò mọ̀,àbí kò ní san án fún eniyangẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀?

-26-

13 Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí pé ó dùn,oyin tí a fún láti inú afárá a sì máa dùn lẹ́nu.

14 Mọ̀ dájú pé bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n yóo rí fún ọ,bí o bá ní i, yóo dára fún ọ lẹ́yìn ọ̀la,ìrètí rẹ kò sì ní di asán.

-27-

15 Má lúgọ bí eniyan burúkú láti kó ilé olódodo,má fọ́ ilé rẹ̀.

16 Nítorí pé bí olódodo bá ṣubú léra léra nígbà meje, yóo tún dìde,ṣugbọn àjálù máa ń bi ẹni ibi ṣubú.

-28-

17 Má yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú,má sì jẹ́ kí inú rẹ dùn bí ó bá kọsẹ̀,

18 kí OLUWA má baà bínú sí ọ tí ó bá rí ọ,kí ó sì yí ojú ibinu rẹ̀ pada kúrò lára ọ̀tá rẹ.

-29-

19 Má ṣe kanra nítorí àwọn aṣebi,má sì ṣe jowú eniyan burúkú,

20 nítorí pé kò sí ìrètí fún ẹni ibi,a óo sì pa àtùpà eniyan burúkú.

-30-

21 Ọmọ mi, bẹ̀rù OLUWA ati ọba,má ṣe àìgbọràn sí ọ̀kankan ninu wọn;

22 nítorí jamba lè ti ọ̀dọ̀ wọn wá lójijì,ta ló mọ irú ìparun, tí ó lè ti ọ̀dọ̀ àwọn mejeeji wá?

Àfikún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n Tẹ̀síwájú sí i

23 Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tún nìwọ̀nyí:Kò dára láti máa ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́.

24 Ẹni tí ó sọ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ mọ́,àwọn eniyan yóo gbé e ṣépè,àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì kórìíra rẹ̀.

25 Ṣugbọn yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá dá ẹ̀bi fún ẹni tí ó jẹ̀bi,ibukun Ọlọrun yóo sì bá wọn.

26 Ẹni tí ó bá fèsì tí ó tọ́dàbí ẹni tí ó fi ẹnu koni lẹ́nu.

27 Parí iṣẹ́ tí ò ń ṣe níta,tọ́jú gbogbo nǹkan oko rẹ,lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.

28 Má jẹ́rìí lòdì sí aládùúgbò rẹ láìnídìí,má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu rẹ jáde.

29 Má sọ pé, “Bí lágbájá ti ṣe sí mi,bẹ́ẹ̀ ni èmi náà yóo ṣe sí i,n óo san ẹ̀san ohun tí ó ṣe fún un.”

30 Mo gba ẹ̀gbẹ́ oko ọ̀lẹ kan kọjá,mo kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà àjàrà ẹnìkan tí kò lóye.

31 Wò ó! Ẹ̀gún ti hù níbi gbogbo,igbó ti bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀,ọgbà tí ó fi òkúta ṣe yí i ká sì ti wó.

32 Mo ṣe àṣàrò lórí ohun tí mo ṣàkíyèsí,mo sì kọ́ ẹ̀kọ́ lára ohun tí mo rí.

33 Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,

34 bẹ́ẹ̀ ni òṣì yóo ṣe dé bá ọbíi kí olè yọ sí eniyan,àìní yóo sì wọlé tọ̀ ọ́ bí ẹni tí ó di ihamọra ogun.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31