Ìwé Òwe 11 BM

1 OLUWA kórìíra òṣùnwọ̀n èké,òṣùnwọ̀n tí ó péye ni inú rẹ̀ dùn sí.

2 Bí ìgbéraga bá wọlé, àbùkù a tẹ̀lé e,ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu àwọn onírẹ̀lẹ̀.

3 Òtítọ́ inú àwọn olódodo a máa tọ́ wọn,ṣugbọn ìwà aiṣootọ àwọn ọ̀dàlẹ̀ níí pa wọ́n.

4 Ọrọ̀ kò jámọ́ nǹkankan ní ọjọ́ ibinu,ṣugbọn òdodo a máa gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú,

5 Òdodo ẹni pípé a máa mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́,ṣugbọn ẹni ibi ṣubú nípa ìwà ìkà rẹ̀.

6 Ìwà òdodo àwọn olóòótọ́ yóo gbà wọ́n,ṣugbọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dàlẹ̀ yóo dè wọ́n nígbèkùn.

7 Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá kú,ìrètí wọn yóo di asán,bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn tí kò mọ Ọlọrun yóo di òfo.

8 OLUWA a máa gba olódodo lọ́wọ́ ìyọnu,ṣugbọn ẹni ibi a bọ́ sinu wahala.

9 Ẹni tí kò mọ Ọlọrun a máafi ẹnu ba ti aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,ṣugbọn nípa ìmọ̀ a máa gba olódodo sílẹ̀.

10 Nígbà tí nǹkan bá ń dára fún olódodo,gbogbo ará ìlú a máa yọ̀,nígbà tí eniyan burúkú bá kú,gbogbo ará ìlú a sì hó ìhó ayọ̀.

11 Ìre tí olódodo bá sú fún ìlú a máa gbé orúkọ ìlú ga,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn eniyan burúkú a máa run ìlú.

12 Ẹni tí ó tẹmbẹlu aládùúgbò rẹ̀ kò gbọ́n,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa pa ẹnu mọ́.

13 Olófòófó a máa tú àṣírí,ṣugbọn ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a máa pa àṣírí mọ́.

14 Níbi tí kò bá ti sí ìtọ́ni, orílẹ̀-èdè a máa ṣubú,ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ọpọlọpọ olùdámọ̀ràn yóo máa gbé ní àìléwu.

15 Ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò yóo rí ìyọnu,ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣe onídùúró yóo wà láìléwu.

16 Obinrin onínúrere gbayì,ṣugbọn ọrọ̀ nìkan ni ìkà yóo ní.

17 Ẹni tí ó ṣoore ṣe é fún ara rẹ̀,ẹni tí ó sì ń ṣìkà ó ń ṣe é fún ara rẹ̀.

18 Owó ọ̀yà èké ni eniyan burúkú óo gbà,ṣugbọn ẹni tí ó bá hùwà òdodo yóo gba èrè òtítọ́.

19 Ẹni tí ó dúró ṣinṣin lórí òdodo yóo yè,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lépa ibi yóo kú.

20 Ẹni ìríra ni àwọn alágàbàgebè lójú OLUWA,ṣugbọn àwọn tí ọ̀nà wọn mọ́ ni ìdùnnú fún un.

21 Dájúdájú ẹni ibi kò ní lọ láìjìyà,ṣugbọn a óo gba àwọn olódodo là.

22 Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ni obinrin tí ó lẹ́wà tí kò ní làákàyè.

23 Ìfẹ́ ọkàn olódodo a máa yọrí sí rere,ṣugbọn ìrètí eniyan burúkú a máa já sí ibinu.

24 Ẹnìkan wà tíí máa ṣe ìtọrẹ àánú káàkiri,sibẹsibẹ àníkún ni ó ń ní,ẹnìkan sì wà tí ó háwọ́,sibẹsibẹ aláìní ni.

25 Ẹni tí ó bá lawọ́ yóo máa ní àníkún,ẹni tí ó bá jẹ́ kí ọkàn ẹlòmíràn balẹ̀,ọkàn tirẹ̀ náà yóo balẹ̀.

26 Ẹni tí ó bá ń kó oúnjẹ pamọ́, yóo gba ègún sórí,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ta oúnjẹ, yóo rí ibukun gbà.

27 Ẹni tí ó bá ń wá ire, yóo rí ojurere,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ibi, ibi yóo bá a.

28 Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóo rẹ̀ dànù bí òdòdó,ṣugbọn olódodo yóo rú bí ewé tútù.

29 Ẹni tí ó bá mú ìyọnu dé bá ìdílé rẹ̀ yóo jogún òfo,òmùgọ̀ ni yóo sì máa ṣe iranṣẹ ọlọ́gbọ́n.

30 Èso olódodo ni igi ìyè,ṣugbọn ìwà aibikita fún òfin a máa paniyan.

31 Bí a óo bá san ẹ̀san fún olódodo láyé,mélòó-mélòó ni ti eniyan burúkú ati ẹlẹ́ṣẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31