11 Bí wọn bá wí pé,“Tẹ̀lé wa ká lọ,kí á lọ sápamọ́ láti paniyan,kí á lúgọ de aláìṣẹ̀,
12 jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyèkí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú,
13 a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó,ilé wa yóo sì kún fún ìkógun.
14 Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa,kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.”
15 Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́,má sì bá wọn rìn,
16 nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí,wọ́n a sì máa yára láti paniyan.
17 Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀,nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni,