16 nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí,wọ́n a sì máa yára láti paniyan.
17 Asán ni àwọ̀n tí eniyan dẹ sílẹ̀,nígbà tí ẹyẹ tí a dẹ ẹ́ fún ń woni,
18 ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè,ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí.
19 Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí,ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn.
20 Ọgbọ́n ń kígbe ní òpópónà,ó ń pariwo láàrin ọjà,
21 ó ń kígbe lórí odi ìlú,ó ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ẹnubodè ìlú, ó ní,
22 “Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ óo ti pẹ́ tó ninu àìmọ̀kan yín?Àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn yóo ti ní inú dídùn pẹ́ tó ninu ẹ̀gàn pípa wọn,tí àwọn òmùgọ̀ yóo sì kórìíra ìmọ̀?