18 ṣugbọn ẹ̀jẹ̀ ara wọn ni irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ lúgọ dè,ìparun ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n lúgọ tí wọn ń retí.
19 Bẹ́ẹ̀ ni ti àwọn tí wọ́n ń fi ipá kó ọrọ̀ jọ rí,ọrọ̀ tí wọn fi ipá kójọ níí gba ẹ̀mí wọn.
20 Ọgbọ́n ń kígbe ní òpópónà,ó ń pariwo láàrin ọjà,
21 ó ń kígbe lórí odi ìlú,ó ń sọ̀rọ̀ ní àwọn ẹnubodè ìlú, ó ní,
22 “Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ óo ti pẹ́ tó ninu àìmọ̀kan yín?Àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn yóo ti ní inú dídùn pẹ́ tó ninu ẹ̀gàn pípa wọn,tí àwọn òmùgọ̀ yóo sì kórìíra ìmọ̀?
23 Ẹ fetí sí ìbáwí mi,n óo ṣí ọkàn mi payá fun yín,n óo sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi ye yín.
24 Nítorí pé mo ti ké títí, kò sì sí ẹni tí ó gbọ́,mo ti na ọwọ́ si yín ṣugbọn kò sí ẹni tí ó dá mi lóhùn,