26 Èmi náà óo sì máa fi yín rẹ́rìn-ínnígbà tí ìdààmú bá dé ba yín,n óo máa fi yín ṣe ẹlẹ́yànígbà tí ìpayà bá dé ba yín.
27 Nígbà tí ìpayà bá dé ba yín bí ìjì,tí ìdààmú dé ba yín bí ìjì líle,tí ìpọ́njú ati ìrora bò yín mọ́lẹ̀.
28 Ẹ óo ké pè mí nígbà náà,ṣugbọn n kò ní dáhùn.Ẹ óo wá mi láìsinmi,ṣugbọn ẹ kò ní rí mi.
29 Nítorí pé ẹ kórìíra ìmọ̀,ẹ kò sì bẹ̀rù OLUWA.
30 Ẹ kò fẹ́ ìmọ̀ràn mi,ẹ sì kẹ́gàn gbogbo ìbáwí mi.
31 Nítorí náà, ẹ óo jèrè iṣẹ́ yín,ìwà burúkú yín yóo sì di àìsàn si yín lára.
32 Àwọn aláìgbọ́n kú nítorí pé wọn kò gba ẹ̀kọ́aibikita àwọn òmùgọ̀ ni yóo pa wọ́n run.