8 Ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ baba rẹ,má sì kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ,
9 nítorí pé ẹ̀kọ́ tí wọn bá kọ́ ọ yóo dàbí adé tí ó lẹ́wà lórí rẹ,ati bí ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.
10 Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,o ò gbọdọ̀ gbà.
11 Bí wọn bá wí pé,“Tẹ̀lé wa ká lọ,kí á lọ sápamọ́ láti paniyan,kí á lúgọ de aláìṣẹ̀,
12 jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyèkí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú,
13 a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó,ilé wa yóo sì kún fún ìkógun.
14 Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa,kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.”