13 Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa ń jáde lẹ́nu ẹni tí ó ní òye,ṣugbọn kùmọ̀ ló yẹ ẹ̀yìn ẹni tí kò gbọ́n.
14 Ọlọ́gbọ́n eniyan a máa wá ìmọ̀ kún ìmọ̀,ṣugbọn ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ máa ń fa ìparun mọ́ra.
15 Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ààbò rẹ̀,ṣugbọn àìní talaka ni yóo pa talaka run.
16 Èrè àwọn olódodo a máa fa ìyè,ṣugbọn èrè àwọn eniyan burúkú a máa fà wọ́n sinu ẹ̀ṣẹ̀.
17 Ẹni tí ó bá gba ìtọ́ni wà ní ọ̀nà ìyè,ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ ìbáwí yóo ṣìnà.
18 Ẹni tí ó di eniyan sinu jẹ́ ẹlẹ́tàn eniyan,ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, òmùgọ̀ ni.
19 Bí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀ jù, àṣìsọ a máa wọ̀ ọ́,ṣugbọn ẹni tí ó bá kó ẹnu ara rẹ̀ ní ìjánu, ọlọ́gbọ́n ni.