14 Níbi tí kò bá ti sí ìtọ́ni, orílẹ̀-èdè a máa ṣubú,ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ọpọlọpọ olùdámọ̀ràn yóo máa gbé ní àìléwu.
15 Ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò yóo rí ìyọnu,ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣe onídùúró yóo wà láìléwu.
16 Obinrin onínúrere gbayì,ṣugbọn ọrọ̀ nìkan ni ìkà yóo ní.
17 Ẹni tí ó ṣoore ṣe é fún ara rẹ̀,ẹni tí ó sì ń ṣìkà ó ń ṣe é fún ara rẹ̀.
18 Owó ọ̀yà èké ni eniyan burúkú óo gbà,ṣugbọn ẹni tí ó bá hùwà òdodo yóo gba èrè òtítọ́.
19 Ẹni tí ó dúró ṣinṣin lórí òdodo yóo yè,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lépa ibi yóo kú.
20 Ẹni ìríra ni àwọn alágàbàgebè lójú OLUWA,ṣugbọn àwọn tí ọ̀nà wọn mọ́ ni ìdùnnú fún un.