1 Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀,ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni.
2 Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi.
3 Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀,ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu.
4 Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀,ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun.
5 Èrò ọkàn olódodo dára,ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.
6 Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là.
7 A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun,ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin.