1 Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,ṣugbọn ẹlẹ́yà kì í gbọ́ ìbáwí.
2 Eniyan rere a máa rí ire nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,ṣugbọn ohun tí àwọn ẹlẹ́tàn ń fẹ́ ni ìwà jàgídíjàgan.
3 Ẹni tí ó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń ṣọ́,ẹni tí ń sọ̀rọ̀ àsọjù yóo parun.
4 Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i,ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan.
5 Olóòótọ́ a máa kórìíra èké,ṣugbọn eniyan burúkú a máa hùwà ìtìjú ati àbùkù.