16 Olóye eniyan a máa fi ìmọ̀ ṣe ohun gbogbo,ṣugbọn òmùgọ̀ a máa fi agọ̀ rẹ̀ yangàn.
17 Iranṣẹ burúkú a máa kó àwọn eniyan sinu wahala,ṣugbọn ikọ̀ tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ a máa mú ìrẹ́pọ̀ wá.
18 Òṣì ati àbùkù ni yóo bá ẹni tí ó kọ ìmọ̀ràn,ṣugbọn ẹni tó bá gba ìbáwí yóo gba iyì.
19 Bí èrò ọkàn ẹni bá ṣẹ, a máa fúnni láyọ̀,ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ kórìíra ati kọ ibi sílẹ̀.
20 Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà.
21 Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣugbọn olódodo yóo máa rí ire.
22 Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́.