20 Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà.
21 Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣugbọn olódodo yóo máa rí ire.
22 Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́.
23 Oko tí talaka dá lè mú ọpọlọpọ oúnjẹ jáde,ṣugbọn àwọn alaiṣootọ níí kó gbogbo rẹ̀ lọ.
24 Ẹni tí kì í bá na ọmọ rẹ̀ kò fẹ́ràn rẹ̀,ṣugbọn ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóo máa bá a wí.
25 Olódodo a máa jẹ àjẹtẹ́rùn,ṣugbọn eniyan burúkú kì í yó.