4 Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́ nǹkan, ṣugbọn kò ní rí i,ṣugbọn ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yóo ní ọpọlọpọ nǹkan.
5 Olóòótọ́ a máa kórìíra èké,ṣugbọn eniyan burúkú a máa hùwà ìtìjú ati àbùkù.
6 Òdodo a máa dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́,ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ a máa bi eniyan burúkú ṣubú.
7 Ẹnìkan ń ṣe bí ọlọ́rọ̀,bẹ́ẹ̀ kò ní nǹkankan,níbẹ̀ ni ẹlòmíràn ń ṣe bíi talaka,ṣugbọn tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.
8 Ọlọ́rọ̀ a máa fi ohun ìní rẹ̀ ra ẹ̀mí rẹ̀ pada,ṣugbọn talaka kì í tilẹ̀ gbọ́ ìbáwí.
9 Ìmọ́lẹ̀ olódodo a máa fi ayọ̀ tàn,ṣugbọn fìtílà eniyan burúkú yóo kú.
10 Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà,ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.