19 Àwọn ẹni ibi yóo tẹríba fún àwọn ẹni rere,àwọn eniyan burúkú yóo sì tẹríba lẹ́nu ọ̀nà àwọn olódodo.
20 Àwọn aládùúgbò talaka pàápàá kórìíra rẹ̀,ṣugbọn ọlọ́rọ̀ a máa ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́.
21 Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀,ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí ó bá ṣàánú talaka.
22 Àwọn tí wọn ń pète ibi ti ṣìnà,ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbèrò ire yóo rí ojurere ati òtítọ́.
23 Kò sí iṣẹ́ kan tí kò lérè,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu lásán láìsí iṣẹ́, a máa sọ eniyan di aláìní.
24 Ọgbọ́n ni adé àwọn ọlọ́gbọ́n,ṣugbọn ìwà aláìgbọ́n jẹ́ yẹ̀yẹ́ àwọn òmùgọ̀.
25 Ẹlẹ́rìí tòótọ́ a máa gba ẹ̀mí là,ṣugbọn ọ̀dàlẹ̀ ni òpùrọ́.