23 Kò sí iṣẹ́ kan tí kò lérè,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu lásán láìsí iṣẹ́, a máa sọ eniyan di aláìní.
24 Ọgbọ́n ni adé àwọn ọlọ́gbọ́n,ṣugbọn ìwà aláìgbọ́n jẹ́ yẹ̀yẹ́ àwọn òmùgọ̀.
25 Ẹlẹ́rìí tòótọ́ a máa gba ẹ̀mí là,ṣugbọn ọ̀dàlẹ̀ ni òpùrọ́.
26 Ninu ìbẹ̀rù OLUWA ni igbẹkẹle tí ó dájú wà,níbẹ̀ ni ààbò wà fún àwọn ọmọ ẹni.
27 Ìbẹ̀rù OLUWA ni orísun ìyè,òun níí mú ká yẹra fún tàkúté ikú.
28 Ọ̀pọ̀ eniyan ni ògo ọba,olórí tí kò bá ní eniyan yóo parun.
29 Ẹni tí kì í báá yára bínú lóye lọpọlọpọ,ṣugbọn onínúfùfù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.