27 Ìbẹ̀rù OLUWA ni orísun ìyè,òun níí mú ká yẹra fún tàkúté ikú.
28 Ọ̀pọ̀ eniyan ni ògo ọba,olórí tí kò bá ní eniyan yóo parun.
29 Ẹni tí kì í báá yára bínú lóye lọpọlọpọ,ṣugbọn onínúfùfù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.
30 Ìbàlẹ̀ ọkàn a máa mú kí ara dá ṣáṣá,ṣugbọn ìlara a máa dá egbò sinu eegun.
31 Ẹni tí ó bá ni talaka lára àbùkù Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni ó ń ta,ṣugbọn ẹni tí ó ṣàánú fún àwọn aláìní ń bu ọlá fún Ẹlẹ́dàá rẹ̀.
32 Eniyan burúkú ṣubú nítorí ìwà ibi rẹ̀,ṣugbọn olódodo rí ààbò nípasẹ̀ òtítọ́ inú rẹ̀.
33 Ọgbọ́n kún inú ẹni tí ó mòye,ṣugbọn kò sí ohun tí ó jọ ọgbọ́n lọ́kàn òmùgọ̀.