10 Ìbáwí pupọ ń bẹ fún ẹni tí ó yapa kúrò ní ọ̀nà rere,ẹni tí ó bá kórìíra ìbáwí yóo kú.
11 Isà òkú ati ìparun kò pamọ́ lójú OLUWA,mélòó-mélòó ni ọkàn eniyan.
12 Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí,kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n.
13 Inú dídùn a máa múni dárayá,ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì.
14 Ẹni tí ó ní òye a máa wá ìmọ̀,ṣugbọn agọ̀ ni oúnjẹ òmùgọ̀.
15 Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú,ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn.
16 Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA,ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ.