13 Inú dídùn a máa múni dárayá,ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì.
14 Ẹni tí ó ní òye a máa wá ìmọ̀,ṣugbọn agọ̀ ni oúnjẹ òmùgọ̀.
15 Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú,ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn.
16 Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA,ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ.
17 Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́,sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.
18 Onínúfùfù a máa rú ìjà sókè,ṣugbọn onínútútù a máa pẹ̀tù sí ibinu.
19 Ẹ̀gún kún bo ọ̀nà ọ̀lẹ,ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí òpópó tí ń dán.