20 Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn,ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ níí kẹ́gàn ìyá rẹ̀.
21 Ayọ̀ ni ìwà òmùgọ̀ jẹ́ fún aláìgbọ́n,ṣugbọn ẹni tí ó ní òye a máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.
22 Àìsí ìmọ̀ràn a máa mú kí ètò dàrú,ṣugbọn ọpọlọpọ ìmọ̀ràn a máa mú kí ó yọrí sí rere.
23 Ìdáhùn kíkún a máa fúnni láyọ̀,kí ọ̀rọ̀ bọ́ sí àsìkò dára lọpọlọpọ!
24 Ọ̀nà ọlọ́gbọ́n lọ tààrà sinu ìyè,kí ó má baà bọ́ sinu isà òkú.
25 OLUWA a máa wó ilé agbéraga,ṣugbọn ó ṣe àmójútó ààlà opó.
26 Ohun ìríra ni èrò ọkàn ẹni ibi lójú OLUWA,ṣugbọn ọrọ̀ àwọn ẹni mímọ́ jẹ́ dídùn inú rẹ̀.