1 Èrò ọkàn ni ti eniyanṣugbọn OLUWA ló ni ìdáhùn.
2 Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó mọ́ lójú ara rẹ̀,ṣugbọn OLUWA ló rí ọkàn.
3 Fi gbogbo àdáwọ́lé rẹ lé OLUWA lọ́wọ́,èrò ọkàn rẹ yóo sì yọrí sí rere.
4 OLUWA a máa jẹ́ kí ohun gbogbo yọrí sí bí ó bá ti fẹ́,ó dá eniyan burúkú fún ọjọ́ ìyọnu.
5 OLUWA kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ agbéraga,dájúdájú kò ní lọ láìjìyà.
6 Àánú ati òtítọ́ a máa ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀,ìbẹ̀rù OLUWA a sì máa mú ibi kúrò.
7 Bí ọ̀nà eniyan bá tẹ́ OLUWA lọ́rùn,a máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá bá a gbé pẹlu alaafia.