11 Ti OLUWA ni òṣùnwọ̀n pípé,iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ohun tí à ń wọ̀n.
12 Àwọn ọba kórìíra ibi ṣíṣe,nítorí nípa òdodo ni a fìdí ìjọba múlẹ̀.
13 Inú ọba a máa dùn sí olódodo,ọba sì máa ń fẹ́ràn àwọn tí ń sọ òtítọ́.
14 Iranṣẹ ikú ni ibinu ọba,ọlọ́gbọ́n eniyan níí tù ú lójú.
15 Ìyè wà ninu ojurere ọba,ojurere rẹ̀ sì dàbí ṣíṣú òjò ní àkókò òjò àkọ́rọ̀.
16 Ó sàn kí eniyan ní òye ju kí ó ní wúrà lọ,ó sì sàn kí eniyan yan ìmọ̀ ju kí ó yan fadaka lọ.
17 Olóòótọ́ kì í tọ ọ̀nà ibi,ẹni tí ń ṣọ́ra, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń pamọ́.