17 Olóòótọ́ kì í tọ ọ̀nà ibi,ẹni tí ń ṣọ́ra, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó ń pamọ́.
18 Ìgbéraga ní ń ṣáájú ìparun,agídí ní ń ṣáájú ìṣubú.
19 Ó sàn kí eniyan jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pẹlu àwọn talakaju kí ó bá agbéraga pín ìkógun lọ.
20 Yóo dára fún ẹni tí ó bá ń gbọ́ràn,ẹni tí ó bá sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ní ayọ̀.
21 Àwọn tí wọ́n gbọ́n ni à ń pè ní amòye,ọ̀rọ̀ tí ó tuni lára a máa yíni lọ́kàn pada.
22 Orísun ìyè ni ọgbọ́n jẹ́ fún àwọn tí wọn ní i,agọ̀ sì jẹ́ ìjìyà fún àwọn òmùgọ̀.
23 Ọgbọ́n inú níí mú kí ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tọ̀nà,ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa yíni lọ́kàn pada.