5 OLUWA kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ agbéraga,dájúdájú kò ní lọ láìjìyà.
6 Àánú ati òtítọ́ a máa ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀,ìbẹ̀rù OLUWA a sì máa mú ibi kúrò.
7 Bí ọ̀nà eniyan bá tẹ́ OLUWA lọ́rùn,a máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá bá a gbé pẹlu alaafia.
8 Ìwọ̀nba ọrọ̀ pẹlu òdodo,sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú lọ.
9 Eniyan lè jókòó kí ó ṣètò ìgbésẹ̀ rẹ̀,ṣugbọn OLUWA níí tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni.
10 Pẹlu ìmísí Ọlọrun ni ọba fi ń sọ̀rọ̀,ìdájọ́ aiṣododo kò gbọdọ̀ ti ẹnu rẹ̀ jáde.
11 Ti OLUWA ni òṣùnwọ̀n pípé,iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ohun tí à ń wọ̀n.