9 Eniyan lè jókòó kí ó ṣètò ìgbésẹ̀ rẹ̀,ṣugbọn OLUWA níí tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni.
10 Pẹlu ìmísí Ọlọrun ni ọba fi ń sọ̀rọ̀,ìdájọ́ aiṣododo kò gbọdọ̀ ti ẹnu rẹ̀ jáde.
11 Ti OLUWA ni òṣùnwọ̀n pípé,iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ohun tí à ń wọ̀n.
12 Àwọn ọba kórìíra ibi ṣíṣe,nítorí nípa òdodo ni a fìdí ìjọba múlẹ̀.
13 Inú ọba a máa dùn sí olódodo,ọba sì máa ń fẹ́ràn àwọn tí ń sọ òtítọ́.
14 Iranṣẹ ikú ni ibinu ọba,ọlọ́gbọ́n eniyan níí tù ú lójú.
15 Ìyè wà ninu ojurere ọba,ojurere rẹ̀ sì dàbí ṣíṣú òjò ní àkókò òjò àkọ́rọ̀.