1 Kí á fi alaafia jẹun, láìsí ọbẹ̀,ó sàn ju kí á máa fi ẹran jẹun pẹlu ìyọnu lọ.
2 Ẹrú tí ó bá mọ ìwà hù, yóo di ọ̀gá lórí ọmọ tí ń hùwà ìbàjẹ́,yóo sì jókòó pín ninu ogún bí ẹni pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ni.
3 Iná ni a fi ń dán fadaka ati wúrà wò,ṣugbọn OLUWA ní ń dán ọkàn wò.
4 Aṣebi a máa tẹ́tí sí ẹni ibi,òpùrọ́ a sì máa fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìkà.
5 Ẹni tí ń fi talaka ṣẹ̀sín, ẹlẹ́dàá talaka ní ń tàbùkù,ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí wahala ẹni ẹlẹ́ni kò ní lọ láìjìyà.
6 Ọmọ ọmọ ni adé arúgbó,òbí sì ni ògo àwọn ọmọ.
7 Ọ̀rọ̀ rere ṣe àjèjì sí ẹnu òmùgọ̀,bẹ́ẹ̀ ni irọ́ pípa kò yẹ àwọn olórí.