3 Iná ni a fi ń dán fadaka ati wúrà wò,ṣugbọn OLUWA ní ń dán ọkàn wò.
4 Aṣebi a máa tẹ́tí sí ẹni ibi,òpùrọ́ a sì máa fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìkà.
5 Ẹni tí ń fi talaka ṣẹ̀sín, ẹlẹ́dàá talaka ní ń tàbùkù,ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí wahala ẹni ẹlẹ́ni kò ní lọ láìjìyà.
6 Ọmọ ọmọ ni adé arúgbó,òbí sì ni ògo àwọn ọmọ.
7 Ọ̀rọ̀ rere ṣe àjèjì sí ẹnu òmùgọ̀,bẹ́ẹ̀ ni irọ́ pípa kò yẹ àwọn olórí.
8 Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ dàbí òògùn ajẹ́-bí-idán lójú ẹni tí ń fúnni,ibi gbogbo tí olúwarẹ̀ bá lọ ni ó ti ń ṣe àṣeyege.
9 Ẹni tí ń dárí ji ni ń wá ìfẹ́,ẹni tí ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ a máa ya ọ̀rẹ́ nípá.