12 yóo máa gbà ọ́ lọ́wọ́ ibi ṣíṣe,ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn,
13 àwọn tí wọ́n ti kọ ọ̀nà òdodo sílẹ̀tí wọn sì ń rìn ninu òkùnkùn;
14 àwọn tí wọn ń yọ̀ ninu ìwà ibití wọ́n sì ní inú dídùn sí ìyapa ibi;
15 àwọn tí ọ̀nà wọn wọ́,tí wọ́n kún fún ìwà àrékérekè.
16 A óo gbà ọ́ lọ́wọ́ obinrin oníṣekúṣe,àní lọ́wọ́ obinrin onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀.
17 Ẹni tí ó kọ ọkọ àárọ̀ rẹ̀ sílẹ̀,tí ó sì gbàgbé majẹmu Ọlọrun rẹ̀.
18 Ẹni tí ilé rẹ̀ rì sinu ìparun,tí ọ̀nà rẹ̀ sì wà ninu ọ̀fìn isà òkú.